Abecedaria Press · Ikọwe Alasopọ
Ẹkọ 16
Lẹta ti a fẹ kọ tẹle ni lẹta e. Lẹta e jẹ ẹya miiran ti lẹta c. Iyatọ pataki ni ibi ti ila isopọ n lọ. Ninu lẹta c, ila isopọ lọ titi de oke lẹta naa patapata, lẹyin naa a yi po, a si kọ c wa. Lẹta e ṣe nnkan to yatọ diẹ. A ṣe ila isopọ wa, lẹyin naa, nitosi oke ila isopọ naa, a yi i soke, lẹyin naa a kọ lẹta c, gẹgẹ bi a ti ṣe tẹlẹ.
Jẹ ki c naa ri roboto daradara. Mo ro pe irisi c ninu apẹẹrẹ yii boya ko roboto to diẹ.
Bakan naa, bi o ba fẹ, ko pọn dandan ki iwaju e ri roboto. O le goke taara pẹlu ila isopọ rẹ, lẹyin naa ki o kọ c rẹ, yoo si ni ṣonṣo kekere kan ni iwaju. Emi yoo fi aworan rẹ han ọ laipẹ.
Ninu Yoruba, ẹ tun wa: kọ e, lẹyin naa fi ila kekere kukuru si isalẹ rẹ.

Ikọwe Alasopọ — Apa Kinni: Awọn Lẹta Kekere · Evan Millner · Published by Abecedaria Press